Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 22:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ṣugbọn bi ọmọbinrin alufa na ba di opó, tabi ẹni-ikọsilẹ, ti kò si lí ọmọ, ti o si pada wá si ile baba rẹ̀, bi ìgba ewe rẹ̀, ki o ma jẹ ninu onjẹ baba rẹ̀: ṣugbọn alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀.

14. Bi ẹnikan ba si jẹ ninu ohun mimọ́ li aimọ̀, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun alufa pẹlu ohun mimọ́ na.

15. Nwọn kò si gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ti nwọn mú fun OLUWA wá:

16. Tabi lati jẹ ki nwọn ki o rù aiṣedede ti o mú ẹbi wá, nigbati nwọn ba njẹ ohun mimọ́ wọn: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.

17. OLUWA si sọ fun Mose pe,

18. Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu awọn alejò ni Israeli, ti o ba fẹ́ ru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ nitori ẹjẹ́ wọn gbogbo, ati nitori ẹbọ rẹ̀ atinuwá gbogbo, ti nwọn nfẹ́ ru si OLUWA fun ẹbọ sisun;

19. Ki o le dà fun nyin, akọ alailabùkun ni ki ẹnyin ki o fi ru u, ninu malu, tabi ninu agutan, tabi ninu ewurẹ.

20. Ṣugbọn ohunkohun ti o ní abùku, li ẹnyin kò gbọdọ múwa: nitoripe ki yio dà fun nyin.

21. Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe sí abùku kan ninu rẹ̀.

22. Afọju, tabi fifàya, tabi eyiti a palara, tabi elegbo, elekuru, tabi oni-ipẹ́, wọnyi li ẹnyin kò gbọdọ fi rubọ si OLUWA, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fi ninu wọn ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA lori pẹpẹ.

23. Ibaṣe akọmalu tabi ọdọ-agutan ti o ní ohun ileke kan, tabi ohun abùku kan, eyinì ni ki iwọ ma fi ru ẹbọ ifẹ́-atinuwá; ṣugbọn fun ẹjẹ́ ki yio dà.

Ka pipe ipin Lef 22