Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 14:18-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o dà si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́: ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA.

19. Ki alufa ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu aimọ́ rẹ̀; lẹhin eyinì ni ki o pa ẹran ẹbọ sisun.

20. Ki alufa ki o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori pẹpẹ: ki alufa ki o ṣètutu fun u, on o si di mimọ́.

21. Bi o ba si ṣe talaka, ti kò le mú tobẹ̃ wá, njẹ ki o mú akọ ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹbi lati fì, lati ṣètutu fun u, ati ọkan ninu idamẹwa òṣuwọn deali iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ, ati òṣuwọn logu oróro kan;

22. Ati àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji, irú eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to; ki ọkan ki o si ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki ekeji ki o si ṣe ẹbọ sisun.

Ka pipe ipin Lef 14