48. Iba ṣe ni ita, tabi ni iwun; ti ọ̀gbọ, tabi ti kubusu; iba ṣe li awọ, tabi ohun kan ti a fi awọ ṣe;
49. Bi àrun na ba ṣe bi ọbẹdo tabi bi pupa lara aṣọ na, tabi lara awọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo awọ kan; àrun ẹ̀tẹ ni, ki a si fi i hàn alufa:
50. Ki alufa ki o si wò àrun na, ki o si sé ohun ti o ní àrun na mọ́ ni ijọ́ meje:
51. Ki o si wò àrun na ni ijọ́ keje: bi àrun na ba ràn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu awọ, tabi ninu ohun ti a fi awọ ṣe; àrun oun ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; alaimọ́ ni.
52. Nitorina ki o fi aṣọ na jóna, iba ṣe ita, tabi iwun, ni kubusu tabi li ọ̀gbọ, tabi ninu ohunèlo awọ kan, ninu eyiti àrun na gbé wà: nitoripe ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; ki a fi jóna.
53. Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na kò ba tàn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe;
54. Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o fọ̀ ohun na ninu eyiti àrun na gbé wà, ki o si sé e mọ́ ni ijọ meje si i.
55. Ki alufa ki o si wò àrun na, lẹhin igbati a fọ̀ ọ tán: si kiyesi i, bi àrun na kò ba pa awọ rẹ̀ dà, ti àrun na kò si ràn si i, alaimọ́ ni; ninu iná ni ki iwọ ki o sun u; o kẹ̀ ninu, iba gbo ninu tabi lode.
56. Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na ba ṣe bi ẹni wodú lẹhin igbati o ba fọ̀ ọ tán; nigbana ni ki o fà a ya kuro ninu aṣọ na, tabi ninu awọ na, tabi ninu ita, tabi ninu iwun:
57. Bi o ba si hàn sibẹ̀ ninu aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe, àrun riràn ni: ki iwọ ki o fi iná sun ohun ti àrun na wà ninu rẹ̀.