Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 13:14-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́.

15. Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni.

16. Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá,

17. Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on.

18. Ara pẹlu, ninu eyi, ani li awọ ara ti õwo ti sọ, ti o si jiná,

19. Ati ni apá õwo na bi iwú funfun ba mbẹ nibẹ̀, tabi àmi didán, funfun ti o si ṣe bi ẹni pọ́n ki a si fi i hàn alufa;

20. Alufa yio wò o, si kiyesi i, li oju rẹ̀ bi o ba jìn jù awọ ara lọ, ti irun rẹ̀ si di funfun, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu õwo na.

21. Ṣugbọn bi alufa na ba wò o, si kiyesi i, ti irun funfun kò si sí ninu rẹ̀, bi kò ba si jìn jù awọ ara lọ, ti o si dabi ẹni wodú, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje:

22. Bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ni.

23. Ṣugbọn bi àmi didán na ba duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn, õwo tita ni; ki alufa ki o si pè e ni mimọ́.

24. Tabi bi ara kan ba mbẹ, ninu awọ ara eyiti ijóni bi iná ba wà, ti ojú jijóna na ba ní àmi funfun didán, ti o ṣe bi ẹni pọn rusurusu tabi funfun;

25. Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi irun ninu àmi didán na ba di funfun, ti o ba si jìn jù awọ ara lọ li oju; ẹ̀tẹ li o ti inu ijóni nì sọ jade; nitorina ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ ni.

26. Ṣugbọn bi alufa ba wò o, si kiyesi i, ti kò sí irun funfun li apá didán na, ti kò si jìn jù awọ ara iyokù lọ, ṣugbọn ti o ṣe bi ẹni ṣújú; nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje:

27. Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́; àrun ẹ̀tẹ ni.

28. Bi àmi didán na ba si duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn si i li awọ ara, ṣugbọn ti o dabi ẹni sújú: iwú ijóni ni, ki alufa ki o si pè e ni mimọ́: nitoripe ijóni tita ni.

29. Bi ọkunrin tabi obinrin kan ba ní àrun li ori rẹ̀ tabi li àgbọn,

30. Nigbana ni ki alufa ki o wò àrun na: si kiyesi i, bi o ba jìn jù awọ ara lọ li oju, bi irun tinrin pupa ba mbẹ ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li aimọ́: ipẹ́ gbigbẹ ni, ani ẹ̀tẹ li ori tabi li àgbọn ni.

Ka pipe ipin Lef 13