Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 10:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nigbana ni Mose wi fun Aaroni pe, Eyiyi li OLUWA wipe, A o yà mi simimọ́ ninu awọn ti nsunmọ mi, ati niwaju awọn enia gbogbo li a o yìn mi li ogo. Aaroni si dakẹ.

4. Mose si pé Miṣaeli ati Elsafani, awọn ọmọ Usieli arakunrin Aaroni, o si wi fun wọn pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ gbé awọn arakunrin nyin kuro niwaju ibi mimọ́ jade sẹhin ibudó.

5. Bẹ̃ni nwọn sunmọ ibẹ̀, nwọn si gbé ti awọn ti ẹ̀wu wọn jade sẹhin ibudó; bi Mose ti wi.

6. Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ máṣe ṣi ibori nyin, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fà aṣọ nyin ya; ki ẹnyin ki o má ba kú, ati ki ibinu ki o má ba wá sori gbogbo ijọ: ṣugbọn ki awọn arakunrin nyin, gbogbo ile Israeli ki o sọkun ijóna ti OLUWA ṣe yi.

7. Ki ẹnyin ki o má si ṣe jade kuro lati ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe oróro itasori OLUWA mbẹ lara nyin. Nwọn si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose.

8. OLUWA si sọ fun Aaroni pe,

9. Máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, iwọ, tabi awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nigbati ẹnyin ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: ìlana ni titilai ni iraniran nyin:

10. Ki ẹnyin ki o le ma fi ìyatọ sãrin mimọ́ ati aimọ́, ati sãrin ẽri ati ailẽri;

11. Ati ki ẹnyin ki o le ma kọ́ awọn ọmọ Israeli ni gbogbo ìlana ti OLUWA ti sọ fun wọn lati ọwọ́ Mose wá.

Ka pipe ipin Lef 10