Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 10:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ATI Nadabu ati Abihu, awọn ọmọ Aaroni, olukuluku nwọn mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari sori wọn, nwọn si mú ajeji iná wá siwaju OLUWA, ti on kò fi aṣẹ fun wọn.

2. Iná si ti ọdọ OLUWA jade, o si run wọn, nwọn si kú niwaju OLUWA.

3. Nigbana ni Mose wi fun Aaroni pe, Eyiyi li OLUWA wipe, A o yà mi simimọ́ ninu awọn ti nsunmọ mi, ati niwaju awọn enia gbogbo li a o yìn mi li ogo. Aaroni si dakẹ.

4. Mose si pé Miṣaeli ati Elsafani, awọn ọmọ Usieli arakunrin Aaroni, o si wi fun wọn pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ gbé awọn arakunrin nyin kuro niwaju ibi mimọ́ jade sẹhin ibudó.

5. Bẹ̃ni nwọn sunmọ ibẹ̀, nwọn si gbé ti awọn ti ẹ̀wu wọn jade sẹhin ibudó; bi Mose ti wi.

6. Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ máṣe ṣi ibori nyin, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fà aṣọ nyin ya; ki ẹnyin ki o má ba kú, ati ki ibinu ki o má ba wá sori gbogbo ijọ: ṣugbọn ki awọn arakunrin nyin, gbogbo ile Israeli ki o sọkun ijóna ti OLUWA ṣe yi.

7. Ki ẹnyin ki o má si ṣe jade kuro lati ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe oróro itasori OLUWA mbẹ lara nyin. Nwọn si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose.

8. OLUWA si sọ fun Aaroni pe,

9. Máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, iwọ, tabi awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nigbati ẹnyin ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: ìlana ni titilai ni iraniran nyin:

10. Ki ẹnyin ki o le ma fi ìyatọ sãrin mimọ́ ati aimọ́, ati sãrin ẽri ati ailẽri;

Ka pipe ipin Lef 10