Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 1:14-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bi o ba si ṣepe ti ẹiyẹ ni ẹbọ sisun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA, njẹ ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá ninu àdaba, tabi ninu ọmọ ẹiyẹle.

15. Ki alufa na ki o si mú u wá si pẹpẹ na, ki o si mi i li ọrùn, ki o si sun u lori pẹpẹ na; ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ki o si ro si ẹba pẹpẹ na.

16. Ki o si fà ajẹsi rẹ̀ já pẹlu ẽri rẹ̀, ki o si kó o lọ si ẹba pẹpẹ na ni ìha ìlà-õrùn, lori ibi ẽru nì:

17. Ki o si là a ti on ti iyẹ́-apa rẹ̀, ṣugbọn ki yio pín i ni meji jalẹ: ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ na, lori igi na ti mbẹ lori iná: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Ka pipe ipin Lef 1