Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joel 3:17-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Bẹ̃li ẹnyin o mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ́ mi: nigbana ni Jerusalemu yio jẹ mimọ́, awọn alejo kì yio si là a kọja mọ.

18. Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu.

19. Egipti yio di ahoro, Edomu yio si di aginju ahoro, nitori ìwa ipá si awọn ọmọ Juda, nitoriti nwọn ti ta ẹjẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ ni ilẹ wọn.

20. Ṣugbọn Juda yio joko titi lai, ati Jerusalemu lati iran de iran.

21. Nitori emi o wẹ̀ ẹjẹ̀ wọn nù, ti emi kò ti wẹ̀nu: nitori Oluwa ngbe Sioni.

Ka pipe ipin Joel 3