Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joel 3:10-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ẹ fi irin ọkọ́ itulẹ̀ nyin rọ idà, ati dojé nyin rọ ọkọ̀: jẹ ki alailera wi pe, Ara mi le koko.

11. Ẹ kó ara nyin jọ, si wá, gbogbo ẹnyin keferi, ẹ si gbá ara nyin jọ yikakiri: nibẹ̀ ni ki o mu awọn alagbara rẹ sọkalẹ, Oluwa.

12. Ẹ ji, ẹ si goke wá si afonifojì Jehoṣafati ẹnyin keferi: nitori nibẹ̀ li emi o joko lati ṣe idajọ awọn keferi yikakiri.

13. Ẹ tẹ̀ doje bọ̀ ọ, nitori ikore pọ́n: ẹ wá, ẹ sọkalẹ; nitori ifunti kún, nitori awọn ọpọ́n kún rekọja, nitori ìwa-buburu wọn pọ̀.

14. Ọ̀pọlọpọ, ọ̀pọlọpọ li afonifojì idajọ, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ ni afonifojì idajọ.

15. Õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, ati awọn irawọ̀ yio fà titàn wọn sẹhin.

16. Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli.

17. Bẹ̃li ẹnyin o mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ́ mi: nigbana ni Jerusalemu yio jẹ mimọ́, awọn alejo kì yio si là a kọja mọ.

18. Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu.

19. Egipti yio di ahoro, Edomu yio si di aginju ahoro, nitori ìwa ipá si awọn ọmọ Juda, nitoriti nwọn ti ta ẹjẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ ni ilẹ wọn.

20. Ṣugbọn Juda yio joko titi lai, ati Jerusalemu lati iran de iran.

Ka pipe ipin Joel 3