Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 36:2-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Bùn mi laye diẹ, emi o si fi hàn ọ, nitori ọ̀rọ sisọ ni o kù fun Ọlọrun.

3. Emi o mu ìmọ mi ti ọ̀na jijin wá, emi o si fi ododo fun Ẹlẹda mi.

4. Nitoripe ọ̀rọ mi kì yio ṣeke nitõtọ, ẹniti o pé ni ìmọ wà pẹlu rẹ.

5. Kiyesi i, Ọlọrun li agbara, kò si gàn ẹnikẹni, o li agbara ni ipá ati oye.

6. On kì ida ẹmi enia buburu sí, ṣugbọn o fi otitọ fun awọn talaka.

7. On kì imu oju rẹ̀ kuro lara olododo, ṣugbọn pẹlu awọn ọba ni nwọn wà lori itẹ; ani o fi idi wọn mulẹ lailai, a si gbe wọn lekè.

8. Bi a ba si dè wọn ninu àba, ti a si fi okun ipọnju dè wọn,

9. Nigbana ni ifi iṣẹ wọn hàn fun wọn, ati irekọja wọn ti nwọn fi gbe ara wọn ga.

10. O ṣi wọn leti pẹlu si ọ̀na ẹkọ́, o si paṣẹ ki nwọn ki o pada kuro ninu aiṣedede.

11. Bi nwọn ba gbagbọ, ti nwọn si sin i, nwọn o lò ọjọ wọn ninu ìrọra, ati ọdun wọn ninu afẹ́.

12. Ṣugbọn bi nwọn kò ba gbagbọ, nwọn o ti ọwọ idà ṣègbe, nwọn a si kú laini oye.

13. Ṣugbọn awọn àgabagebe li aiya kó ibinu jọ; nwọn kò kigbe nigbati o ba dè wọn.

Ka pipe ipin Job 36