Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 36:14-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nigbana ni ọkàn wọn yio kú li ewe, ẹmi wọn a si wà ninu awọn oniwa Sodomu.

15. On gba otoṣi ninu ipọnju rẹ̀, a si ṣi wọn li eti ninu inilara.

16. Bẹ̃ni pẹlupẹlu o si dẹ̀ ọ lọ lati inu ihagaga si ibi gbõrò, ti kò ni wahala ninu rẹ̀; ati ohun ti a si gbe kalẹ ni tabeli rẹ, a jẹ kiki ọ̀ra.

17. Ṣugbọn iwọ kún fun idajọ awọn enia buburu; idajọ ati otitọ di ọ mu.

18. Nitori ibinu mbẹ, ṣọra ki titó rẹ ma bà tàn ọ lọ; má si ṣe jẹ ki titobi irapada mu ọ ṣìna.

19. Ọrọ̀ rẹ pọ̀ to, ti wahala kì yio fi de ba ọ bi? tabi ipá agbara rẹ?

20. Má ṣe ifẹ oru, nigbati a nke awọn orilẹ-ède kuro ni ipo wọn.

21. Ma ṣọra ki iwọ ki o má yi ara rẹ pada si asan, nitori eyi ni iwọ ti ṣàyan jù sũru lọ.

22. Kiyesi i, Ọlọrun a gbeni ga nipa agbara rẹ̀, tani jẹ olukọni bi on?

23. Tali o là ọ̀na-iṣẹ rẹ̀ silẹ fun u, tabi tali o lè wipe, Iwọ ti nṣe aiṣedede?

24. Ranti ki iwọ ki o gbe iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti enia ima kọrin si.

25. Olukuluku enia a ma ri i, ẹni-ikú a ma wò o li okere.

26. Kiyesi i, Ọlọrun tobi, awa kò si mọ̀ bi o ti tobi to! bẹ̃ni a kò le wadi iye ọdun rẹ̀ ri.

27. Nitoripe on li o fa ikán omi ojo silẹ, ki nwọn ki o kán bi ojo ni ikuku rẹ̀.

28. Ti awọsanma nrọ̀, ti o si nfi sẹ̀ lọpọlọpọ lori enia.

29. Pẹlupẹlu ẹnikẹni le imọ̀ itanká awọsanma, tabi ariwo agọ rẹ̀?

Ka pipe ipin Job 36