Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 7:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Dide; ẽṣe ti iwọ fi doju rẹ bolẹ bayi?

11. Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn.

12. Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin.

13. Dide, yà awọn enia na simimọ́, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israeli: iwọ ki yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun ìyasọtọ na kuro ninu nyin.

14. Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan.

15. Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli.

Ka pipe ipin Joṣ 7