Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 5:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli.

2. Nigbana li OLUWA wi fun Joṣua pe, Fi okuta ṣe abẹ ki iwọ ki o si tun kọ awọn ọmọ Israeli nilà lẹ̃keji.

3. Joṣua si ṣe abẹ okuta, o si kọ awọn ọmọ Israeli nilà, ni Gibeati-haaralotu.

4. Idí rẹ̀ li eyi ti Joṣua fi kọ wọn nilà: gbogbo awọn enia ti o ti Egipti jade wá, ti o ṣe ọkunrin, ani gbogbo awọn ọmọ-ogun, nwọn kú li aginjù, li ọ̀na, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni Egipti.

5. Nitori gbogbo awọn enia ti o jade ti ibẹ̀ wà, a kọ wọn nilà: ṣugbọn gbogbo awọn enia ti a bi li aginjù li ọ̀na, bi nwọn ti jade kuro ni Egipti, awọn ni a kò kọnilà.

Ka pipe ipin Joṣ 5