Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 24:26-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Joṣua si kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwé ofin Ọlọrun, o si mú okuta nla kan, o si gbé e kà ibẹ̀ labẹ igi-oaku kan, ti o wà ni ibi-mimọ́ OLUWA.

27. Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin.

28. Bẹ̃ni Joṣua jọwọ awọn enia na lọwọ lọ, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀.

29. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún.

30. Nwọn si sin i ni àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnatisera, ti mbẹ ni ilẹ òke Efraimu, ni ìha ariwa òke Gaaṣi.

31. Israeli si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, ti o si mọ̀ gbogbo iṣẹ OLUWA, ti o ṣe fun Israeli.

Ka pipe ipin Joṣ 24