Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 22:16-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Bayi ni gbogbo ijọ OLUWA wi, Ẹ̀ṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israeli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni?

17. Ẹ̀ṣẹ ti Peori kò to fun wa kọ́, ti a kò ti iwẹ̀mọ́ ninu rẹ̀ titi di oni, bi o tilẹ ṣe pe ajakalẹ-àrun wà ninu ijọ OLUWA,

18. Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli.

19. Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.

20. Ṣe bẹ̃ni Akani ọmọ Sera da ẹ̀ṣẹ niti ohun ìyasọtọ, ti ibinu si dé sori gbogbo ijọ Israeli? ọkunrin na kò nikan ṣegbé ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

21. Nigbana ni awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse dahùn, nwọn si wi fun awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli pe,

22. OLUWA, Ọlọrun awọn ọlọrun, OLUWA Ọlọrun awọn ọlọrun, On mọ̀, Israeli pẹlu yio si mọ̀; bi o ba ṣepe ni ìṣọtẹ ni, tabi bi ni irekọja si OLUWA, (má ṣe gbà wa li oni,)

Ka pipe ipin Joṣ 22