24. Aijaloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.
25. Ati ninu àbọ ẹ̀ya Manasse, Taanaki pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji.
26. Gbogbo ilu na jasi mẹwa pẹlu àgbegbe wọn fun idile awọn ọmọ Kohati ti o kù.
27. Ati awọn ọmọ Gerṣoni, idile awọn ọmọ Lefi, ni nwọn fi Golani ni Baṣani fun pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; lati inu ẹ̀ya Manasse, ati Be-eṣtera pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji.
28. Ati ninu ẹ̀ya Issakari, Kiṣioni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Dabarati pẹlu àgbegbe rẹ̀;
29. Jarmutu pẹlu àgbegbe rẹ̀, Engannimu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.
30. Ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, Miṣali pẹlu àgbegbe rẹ̀, Abdoni pẹlu àgbegbe rẹ̀;
31. Helkati pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Rehobu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.
32. Ati lati inu ẹ̀ya Naftali, Kedeṣi ni Galili pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Hammotu-dori pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Kartani pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹta.
33. Gbogbo ilu awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu ileto wọn.
34. Ati fun idile awọn ọmọ Merari, awọn ọmọ Lefi ti o kù, ni Jokneamu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Karta pẹlu àgbegbe rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni,
35. Dimna pẹlu àgbegbe rẹ̀, Nahalali pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.
36. Ati ninu ẹ̀ya Reubeni, Beseri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jahasi pẹlu àgbegbe rẹ̀,