Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 18:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn.

2. Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn.

3. Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin?

4. Ẹ yàn ọkunrin mẹta fun ẹ̀ya kọkan: emi o si rán wọn, nwọn o si dide, nwọn o si là ilẹ na já, nwọn o si ṣe apejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ilẹ-iní wọn; ki nwọn ki o si pada tọ̀ mi wá.

5. Nwọn o si pín i si ọ̀na meje: Juda yio ma gbé ilẹ rẹ̀ ni gusù, ile Josefu yio si ma gbé ilẹ wọn ni ariwa.

6. Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa.

7. Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn.

8. Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo.

Ka pipe ipin Joṣ 18