Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 13:21-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ati gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, ti Mose kọlù pẹlu awọn ọmọ alade Midiani, Efi, ati Rekemu, ati Suri, ati Huri, ati Reba, awọn ọmọ alade Sihoni, ti ngbé ilẹ na.

22. Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa.

23. Ati àla awọn ọmọ Reubeni ni Jordani, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni ilẹ iní awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi idile wọn, awọn ilu ati ileto wọn.

24. Mose si fi ilẹ fun ẹ̀ya Gadi, ani fun awọn ọmọ Gadi, gẹgẹ bi idile wọn.

25. Àla wọn bẹ̀rẹ ni Jaseri, ati gbogbo ilu Gileadi, ati àbọ ilẹ awọn ọmọ Ammoni, titi dé Aroeri ti mbẹ niwaju Rabba;

26. Ati lati Heṣboni titi dé Ramatu-mispe, ati Betonimu; ati lati Mahanaimu titi dé àgbegbe Debiri;

27. Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn.

28. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọn ati ileto wọn.

29. Mose si fi ilẹ-iní fun àbọ ẹ̀ya Manasse: o si jẹ́ ti àbọ ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse gẹgẹ bi idile wọn.

30. Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Mahanaimu lọ, gbogbo Baṣani, gbogbo ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ilu Jairi, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu:

31. Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn.

32. Wọnyi li awọn ilẹ-iní na ti Mose pín ni iní ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, li apa keji Jordani, lẹba Jeriko ni ìha ìla-õrùn.

33. Ṣugbọn ẹ̀ya Lefi ni Mose kò fi ilẹ-iní fun: OLUWA, Ọlọrun Israeli, ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Ka pipe ipin Joṣ 13