Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 13:2-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri;

3. Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù:

4. Gbogbo ilẹ awọn ara Kenaani, ati Meara ti awọn ara Sidoni, dé Afeki, titi dé àgbegbe awọn Amori:

5. Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati:

6. Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ.

7. Njẹ nitorina pín ilẹ yi ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.

8. Pẹlu rẹ̀ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ti gbà ilẹ-iní wọn, ti Mose fi fun wọn ni ìha keji Jordani ni ìha ìla õrùn, bi Mose iranṣẹ OLUWA ti fi fun wọn;

9. Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji na, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ Medeba titi dé Diboni;

10. Ati gbogbo ilu Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, titi dé àgbegbe awọn ọmọ Ammoni:

11. Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka;

12. Gbogbo ilẹ ọba Ogu ni Baṣani, ti o jọba ni Aṣtarotu ati ni Edrei, ẹniti o kù ninu awọn Refaimu iyokù: nitori awọn wọnyi ni Mose kọlù, ti o si lé jade.

13. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli kò lé awọn Geṣuri, tabi awọn Maakati jade: ṣugbọn awọn Geṣuri ati awọn Maakati ngbé ãrin awọn ọmọ Israeli titi di oni.

14. Kìki ẹ̀ya Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun; ẹbọ OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti a fi iná ṣe ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Ka pipe ipin Joṣ 13