Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 1:13-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ranti ọ̀rọ ti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin pe, OLUWA Ọlọrun nyin nfun nyin ni isimi, on o si fun nyin ni ilẹ yi.

14. Awọn obinrin nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, yio joko ni ilẹ ti Mose fi fun nyin ni ìha ihin Jordani; ṣugbọn ẹnyin o gòke lọ niwaju awọn arakunrin nyin ni ihamọra, gbogbo awọn alagbara akọni, ẹnyin o si ràn wọn lọwọ,

15. Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i.

16. Nwọn si da Joṣua lohùn, wipe, Gbogbo ohun ti iwọ palaṣẹ fun wa li awa o ṣe, ibikibi ti iwọ ba rán wa lọ, li awa o lọ.

17. Gẹgẹ bi awa ti gbọ́ ti Mose li ohun gbogbo, bẹ̃li awa o gbọ́ tirẹ: kìki ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o wà pẹlu rẹ, gẹgẹ bi o ti wà pẹlu Mose.

18. Ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ti o ba tapá si ofin rẹ, ti ki yio si gbọ́ ọ̀rọ rẹ li ohun gbogbo ti iwọ palaṣẹ fun u, pipa li a o pa a: kìki ki iwọ ṣe giri ki o si mu àiya le.

Ka pipe ipin Joṣ 1