Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 9:15-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi; sa wò o, awọn enia yi pãpa ni emi o fi wahala bọ́, emi o si mu wọn mu omi orõro.

16. Emi o si tú wọn ka ninu awọn keferi, ti awọn tikarawọn ati baba wọn kò mọ ri, emi o si rán idà si wọn titi emi o fi run wọn.

17. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá.

18. Ki nwọn ki o si yara, ki nwọn pohùnrere ẹkun fun wa, ki oju wa ki o le sun omije ẹkun, ati ki ipenpeju wa le tu omi jade.

19. Nitori a gbọ́ ohùn ẹkun lati Sioni, pe, A ti pa wa run to! awa dãmu jọjọ, nitoriti a kọ̀ ilẹ yi silẹ, nitoriti ibugbe wa tì wa jade.

20. Njẹ ẹnyin obinrin, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹ jẹ ki eti nyin gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀, ki ẹ si kọ́ ọmọbinrin nyin ni ẹkun, ati ki olukuluku obinrin ki o kọ́ aladugbo rẹ̀ ni arò.

21. Nitori iku ti de oju ferese wa, o ti wọ̀ inu ãfin wa, lati ke awọn ọmọ-ọmu kuro ni ita, ati awọn ọmọdekunrin kuro ni igboro.

22. Sọ pe, Bayi li Oluwa wi, Okú enia yio ṣubu bi àtan li oko, ati bi ibukunwọ lẹhin olukore, ti ẹnikan ko kojọ.

23. Bayi li Oluwa wi, ki ọlọgbọ́n ki o má ṣogo nitori ọgbọ́n rẹ̀, bẹ̃ni ki alagbara ki o má ṣogo nitori agbara rẹ̀, ki ọlọrọ̀ ki o má ṣogo nitori ọrọ̀ rẹ̀.

24. Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yio ba ma ṣogo, ki o ṣe e ninu eyi pe: on ni oye, on si mọ̀ mi; pe, Emi li Oluwa ti nṣe ãnu ati idajọ ati ododo li aiye: nitori inu mi dùn ninu ohun wọnyi, li Oluwa wi.

25. Sa wò o, ọjọ mbọ̀ li Oluwa wi, ti emi o jẹ gbogbo awọn ti a kọ ni ilà pẹlu awọn alaikọla ni ìya;

26. Egipti ati Juda ati Edomu, ati awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, pẹlu gbogbo awọn ti ndá òṣu, ti ngbe aginju: nitori alaikọla ni gbogbo orilẹ-ède yi, ṣugbọn gbogbo ile Israeli jẹ alaikọla ọkàn.

Ka pipe ipin Jer 9