Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 8:2-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nwọn o si tẹ́ wọn siwaju õrùn ati òṣupa ati gbogbo ogun ọrun, ti nwọn ti fẹ, ti nwọn si ti sìn, awọn ti nwọn si rìn tọ̀ lẹhin, ti nwọn si wá, ti nwọn si foribalẹ fun: a kì yio kó wọn jọ, bẹ̃li a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan li oju ilẹ-aiye.

3. Awon iyokù ti o kù ninu idile buburu yi yio yan kikú jù yiyè lọ: ni ibi gbogbo ti nwọn kù si, ti emi ti tì wọn jade si, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

4. Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; enia le ṣubu li aidide mọ? tabi enia le pada, ki o má tun yipada mọ?

5. Ẽṣe ti awọn enia Jerusalemu yi sọ ipadasẹhin di ipẹhinda lailai? nwọn di ẹ̀tan mu ṣinṣin, nwọn kọ̀ lati pada.

6. Mo tẹti lélẹ, mo si gbọ́, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ titọ: kò si ẹnikan ti o ronupiwada buburu rẹ̀ wipe, kili emi ṣe? gbogbo nwọn yipo li ọ̀na wọn, bi akọ-ẹṣin ti nsare gburu sinu ogun.

Ka pipe ipin Jer 8