Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 7:18-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Awọn ọmọ ko igi jọ, awọn baba nda iná, awọn obinrin npò akara lati ṣe akara didùn fun ayaba-ọrun ati lati tú ẹbọ-ọrẹ mimu jade fun ọlọrun miran, ki nwọn ki o le rú ibinu mi soke.

19. Ibinu mi ni nwọn ha ru soke bi? li Oluwa wi, kì ha ṣe si ara wọn fun rudurudu oju wọn?

20. Nitorina bayi li Ọlọrun Oluwa wi, sa wò o, a o dà ibinu ati irunu mi si ibi yi, sori enia ati sori ẹranko, ati sori igi igbo, ati sori eso ilẹ, yio si jo, a kì o le pa iná rẹ̀.

21. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, kó ẹbọ sisun nyin pẹlu ẹbọ jijẹ nyin, ki ẹ si jẹ ẹran.

22. Nitori emi kò wi fun awọn baba nyin, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn ni ọjọ ti mo mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti niti ẹbọ sisun tabi ẹbọ jijẹ:

23. Ṣugbọn eyi ni mo paṣẹ fun wọn wipe, Gba ohùn mi gbọ́, emi o si jẹ Ọlọrun nyin, ẹnyin o si jẹ enia mi: ki ẹ si rin ni gbogbo ọ̀na ti mo ti paṣẹ fun nyin, ki o le dara fun nyin.

24. Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹ eti silẹ, nwọn si rin ni ìmọ ati agidi ọkàn buburu wọn, nwọn si kọ̀ ẹ̀hin wọn kì iṣe oju wọn si mi.

25. Lati ọjọ ti baba nyin ti ilẹ Egipti jade wá titi di oni, emi ti rán gbogbo iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, lojojumọ emi dide ni kutukutu, emi si rán wọn.

26. Sibẹ nwọn kò gbọ́ temi, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ, sugbọn nwọn mu ọrun le, nwọn ṣe buburu jù awọn baba wọn lọ.

27. Bi iwọ ba si wi gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, nwọn kì yio gbọ́ tirẹ: iwọ o si pè wọn, ṣugbọn nwọn kì o da ọ lohùn.

28. Iwọ o si wi fun wọn pe: Eyi ni enia na ti kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò gba ẹkọ́: otitọ ṣègbe, a si ke e kuro li ẹnu wọn.

29. Fá irun ori rẹ, ki o si sọ ọ nù, ki o si sọkun lori oke: nitori Oluwa ti kọ̀ iran ibinu rẹ̀ silẹ, o si ṣa wọn tì.

30. Nitori awọn ọmọ Juda ti ṣe buburu niwaju mi, li Oluwa wi; nwọn ti gbe ohun irira wọn kalẹ sinu ile ti a pe li orukọ mi, lati ba a jẹ.

31. Nwọn si ti kọ́ ibi giga Tofeti, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati sun awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin wọn ninu iná; aṣẹ eyiti emi kò pa fun wọn, bẹ̃ni kò si wá si inu mi.

32. Nitorina sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti a kì o pe e ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn a o pe e ni afonifoji ipakupa: nitori nwọn o sin oku ni Tofeti, titi àye kì yio si mọ.

Ka pipe ipin Jer 7