Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 7:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá wipe:

2. Duro ni ẹnu ilẹkun ile Oluwa, ki o si kede ọ̀rọ yi wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin ti Juda ti ẹ wọ̀ ẹnu ilẹkun wọnyi lati sin Oluwa.

3. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe, emi o si jẹ ki ẹnyin ma gbe ibi yi.

4. Ẹ máṣe gbẹkẹle ọ̀rọ eke, wipe: Tempili Oluwa, Tempili Oluwa, Tempili Oluwa ni eyi!

5. Nitori bi ẹnyin ba tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe nitõtọ; ti ẹnyin ba ṣe idajọ otitọ jalẹ, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀.

6. Ti ẹnyin kò ba si ṣẹ́ alejo ni iṣẹ́, alainibaba ati opó, ti ẹnyin kò si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ni ibi yi, ti ẹnyin kò si rìn tọ ọlọrun miran si ipalara nyin.

7. Nigbana ni emi o mu nyin gbe ibi yi, ni ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin lai ati lailai.

8. Sa wò o, ẹnyin gbẹkẹle ọ̀rọ eke, ti kò ni ère.

9. Kohaṣepe, ẹnyin njale, ẹ npania, ẹ nṣe panṣaga, ẹ nbura eke, ẹ nsun turari fun Baali, ẹ si nrin tọ ọlọrun miran ti ẹnyin kò mọ̀?

10. Ẹnyin si wá, ẹ si duro niwaju mi ni ile yi, ti a fi orukọ mi pè! ẹnyin si wipe: Gbà wa, lati ṣe gbogbo irira wọnyi?

11. Ile yi, ti ẹ fi orukọ mi pè, o ha di iho olè li oju nyin? sa wò o, emi tikarami ti ri i, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 7