Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 6:21-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ohun idugbolu siwaju awọn enia yi, ti baba ati awọn ọmọ yio jumọ ṣubu lù wọn, aladugbo ati ọrẹ rẹ̀ yio ṣegbe.

22. Bayi li Oluwa wi, sa wò o, enia kan ti ilu ariwa wá, ati orilẹ-ède nla kan yio ti opin ilẹ aiye dide wá.

23. Nwọn di ọrun ati ọ̀kọ mu; onroro ni nwọn, nwọn kò ni ãnu; ohùn wọn yio hó bi okun; nwọn gun ẹṣin; nwọn si mura bi ọkunrin ti yio ja ọ logun, iwọ ọmọbinrin Sioni.

24. Awa ti gbọ́ òkiki eyi na: ọwọ wa di rirọ, ẹ̀dun ti di wa mu, ati irora bi obinrin ti nrọbi.

25. Máṣe lọ si inu oko, bẹ̃ni ki o má si rin oju ọ̀na na, nitori idà ọ̀ta, idagiri wà yikakiri.

26. Iwọ, ọmọbinrin enia mi, di ara rẹ ni amure aṣọ-ọ̀fọ ki o si ku ẽru sara, ṣe ọ̀fọ bi ẹniti nṣọ̀fọ fun ọmọ rẹ̀ nikanṣoṣo, pohùnrere kikoro: nitori afiniṣe-ijẹ yio ṣubu lù wa lojiji.

27. Emi ti fi ọ ṣe ẹniti o ma dán ni wò, odi alagbara lãrin enia mi, ki iwọ ki o le mọ̀ ki o si le dan ọ̀na wọn wò.

28. Gbogbo nwọn ni alagidi ọlọtẹ̀, ti nrin kiri sọ̀rọ̀ ẹni lẹhin, idẹ ati irin ni nwọn; abanijẹ ni gbogbo nwọn iṣe.

29. Ẹwìri joná, iná ti jẹ ojé, ẹniti nyọ ọ, nyọ ọ lasan, a kò si ya enia buburu kuro.

30. Fàdaka bibajẹ ni enia yio ma pè wọn, nitori Oluwa ti kọ̀ wọn silẹ.

Ka pipe ipin Jer 6