Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 52:22-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ati ọna-ori idẹ wà lori rẹ̀; giga ọna-ori kan si ni igbọnwọ marun, pẹlu iṣẹ wiwun ati pomegranate lara ọna ori wọnni yikakiri, gbogbo rẹ̀ jẹ ti idẹ: gẹgẹ bi wọnyi ni ọwọ̀n ekeji pẹlu, ati pomegranate rẹ̀.

23. Pomegranate mẹrindilọgọrun li o wà ni gbangba: gbogbo pomegranate lori iṣẹ wiwun na jẹ ọgọrun yikakiri.

24. Balogun iṣọ si mu Seraiah, olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah, alufa keji, ati awọn oluṣọ iloro mẹta:

25. Ati lati inu ilu o mu iwẹfa kan, ti o ni itọju awọn ologun; ati awọn ọkunrin meje ti nwọn nduro niwaju ọba, ti a ri ni ilu na; ati akọwe olori ogun ẹniti ntò awọn enia ilẹ na; ati ọgọta enia ninu awọn enia ilẹ na, ti a ri li ãrin ilu na.

26. Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu wọn, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla.

27. Ọba Babeli si kọlu wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.

28. Eyi li awọn enia ti Nebukadnessari kó ni ìgbekun lọ: li ọdun keje, ẹgbẹdogun o le mẹtalelogun ara Juda.

29. Li ọdun kejidilogun Nebukadnessari, o kó ẹgbẹrin enia o le mejilelọgbọn ni igbèkun lati Jerusalemu lọ:

30. Li ọdun kẹtalelogun Nebukadnessari, Nebusaradani, balogun iṣọ, kó ọtadilẹgbẹrin enia o di marun awọn ara Juda ni igbekun lọ: gbogbo awọn enia na jẹ ẹgbẹtalelogun.

31. O si ṣe, li ọdun kẹtadilogoji Jehoiakimu, ọba Juda, li oṣu kejila, li ọjọ kẹdọgbọn oṣu, Efil-Merodaki, ọba Babeli, li ọdun ekini ijọba rẹ̀, o gbe ori Jehoiakimu, ọba Juda, soke, o si mu u jade ninu ile túbu.

32. O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbe itẹ rẹ̀ ga jù itẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli.

33. O si parọ aṣọ túbu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

34. Ati ipin onjẹ rẹ̀, ipin onjẹ igbagbogbo, ti ọba Babeli nfi fun u lojojumọ ni ipin tirẹ̀, titi di ọjọ ikú rẹ̀, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

Ka pipe ipin Jer 52