Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 50:25-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Oluwa ti ṣi ile ohun-ijà rẹ̀ silẹ; o si ti mu ohun-elo ikannu rẹ̀ jade: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni iṣẹ́ iṣe ni ilẹ awọn ara Kaldea.

26. Ẹ wá sori rẹ̀ lati opin gbogbo, ṣi ile iṣura rẹ̀ silẹ: ẹ kó o jọ bi òkiti, ki ẹ si yà a sọtọ fun iparun, ẹ máṣe fi iyokù silẹ fun u!

27. Pa gbogbo awọn akọ-malu rẹ̀! nwọn o lọ si ibi pipa: ègbe ni fun wọn! nitori ọjọ wọn de, àkoko ibẹwo wọn.

28. Ohùn awọn ti o salọ, ti o si sala lati ilẹ Babeli wá, lati kede igbẹsan Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni, igbẹsan tempili rẹ̀!

29. Pè ọ̀pọlọpọ enia, ani gbogbo tafatafa, sori Babeli, ẹ dótì i yikakiri; má jẹ ki ẹnikan sala: san fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i, nitoriti o ti gberaga si Oluwa, si Ẹni-Mimọ Israeli.

30. Nitorina ni awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ologun rẹ̀ li a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa wi.

31. Wò o, emi dojukọ ọ! iwọ agberaga, li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, wi: nitori ọjọ rẹ de, àkoko ti emi o bẹ̀ ọ wò.

32. Agberaga yio kọsẹ, yio si ṣubu, ẹnikan kì o si gbe e dide: emi o si da iná ni ilu rẹ̀, yio si jo gbogbo ohun ti o yi i kakiri.

33. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda li a jumọ pọn loju pọ̀: gbogbo awọn ti o kó wọn ni ìgbekun si di wọn mu ṣinṣin; nwọn kọ̀ lati jọ wọn lọwọ lọ.

34. Ṣugbọn Olurapada wọn lagbara; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: ni jijà yio gba ijà wọn jà! ki o le mu ilẹ na simi, ki o si mu awọn olugbe Babeli wariri.

35. Ida lori awọn ara Kaldea, li Oluwa wi, ati lori awọn olugbe Babeli, ati lori awọn ijoye rẹ̀, ati lori awọn ọlọgbọn rẹ̀?

36. Idà lori awọn ahalẹ nwọn o si ṣarán: idà lori awọn alagbara rẹ̀; nwọn o si damu.

37. Idà lori awọn ẹṣin rẹ̀, ati lori awọn kẹ̀kẹ ati lori gbogbo awọn àjeji enia ti o wà lãrin rẹ̀; nwọn o si di obinrin: idà lori iṣura rẹ̀; a o si kó wọn lọ.

38. Ọda lori omi odò rẹ̀; nwọn o si gbẹ: nitori ilẹ ere fifin ni, nwọn si nṣogo ninu oriṣa wọn.

39. Nitorina awọn ẹran-iju pẹlu ọ̀wawa ni yio ma gbe ibẹ̀, abo ògongo yio si ma gbe inu rẹ̀, a kì o si gbe inu rẹ̀ mọ lailai; bẹ̃ni a kì o ṣatipo ninu rẹ̀ lati irandiran.

40. Gẹgẹ bi Ọlọrun ti bì Sodomu ati Gomorra ṣubu ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; bẹ̃ni enia kan kì o gbe ibẹ, tabi ọmọ enia kan kì o ṣatipo ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Jer 50