Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 50:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti Oluwa sọ si Babeli ati si ilẹ awọn ara Kaldea nipa ẹnu Jeremiah woli.

2. Ẹ sọ ọ lãrin awọn orilẹ-ède, ẹ si kede, ki ẹ si gbe asia soke: ẹ kede, ẹ má si ṣe bò o: wipe, a kó Babeli, oju tì Beli, a fọ Merodaki tutu; oju tì awọn ere rẹ̀, a fọ awọn òriṣa rẹ̀ tutu.

3. Nitori lati ariwa ni orilẹ-ède kan ti wá sori rẹ̀, ti yio sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ẹnikan kì o gbe inu rẹ̀: nwọn o sa, nwọn o lọ, ati enia ati ẹranko.

4. Li ọjọ wọnni ati li àkoko na, li Oluwa wi, awọn ọmọ Israeli yio jumọ wá, awọn, ati awọn ọmọ Juda, nwọn o ma lọ tẹkúntẹkún: nwọn o lọ, nwọn o si ṣafẹri Oluwa Ọlọrun wọn.

5. Nwọn o ma bère ọ̀na Sioni, oju wọn yio si yi sibẹ, nwọn o wá, nwọn o darapọ mọ Oluwa ni majẹmu aiyeraiye, ti a kì yio gbagbe.

Ka pipe ipin Jer 50