Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 49:22-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Wò o, yio goke wá yio si fò gẹgẹ bi idì, yio si nà iyẹ rẹ̀ sori Bosra: ati li ọjọ na ni ọkàn awọn alagbara ọkunrin Edomu yio dabi ọkàn obinrin ni irọbi.

23. Si Damasku. Oju tì Hamati, ati Arpadi: nitori nwọn ti gbọ́ ìhin buburu: aiya ja wọn; idãmu wà lẹba okun; nwọn kò le ri isimi.

24. Damasku di alailera, o yi ara rẹ̀ pada lati sa, iwarìri si dì i mu: ẹ̀dun ati irora ti dì i mu, gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi.

25. Bawo ni a kò ṣe fi ilu iyìn silẹ, ilu ayọ̀ mi!

26. Nitorina awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ọkunrin ogun ni a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

27. Emi o si da iná ni odi Damasku, yio si jo ãfin Benhadadi run.

28. Si Kedari, ati si ijọba Hasori, ti Nebukadnessari ọba Babeli, kó: Bayi li Oluwa wi; Dide, goke lọ si Kedari, ki ẹ si pa awọn ọkunrin ìla-õrùn run.

29. Agọ wọn ati agbo-ẹran wọn ni nwọn o kó lọ: nwọn o mu aṣọ agọ wọn fun ara wọn, ati gbogbo ohun-èlo wọn, ati ibakasiẹ wọn; nwọn o si kigbe sori wọn pe, Ẹ̀ru yikakiri!

30. Sa, yara salọ, fi ara pamọ si ibi jijìn, ẹnyin olugbe Hasori, li Oluwa wi; nitori Nebukadnessari ọba Babeli, ti gbìmọ kan si nyin, o si ti gba èro kan si nyin.

31. Dide, goke lọ sọdọ orilẹ-ède kan ti o wà ni irọra, ti o ngbe li ailewu, li Oluwa wi, ti kò ni ilẹkun ẹnu-bode tabi ikere; ti ngbe fun ara rẹ̀.

32. Ibakasiẹ wọn yio si di ikogun, ati ọ̀pọlọpọ ẹran-ọ̀sin wọn yio di ijẹ: emi o si tú awọn ti nda òṣu ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ; emi o si mu wahala wọn de lati iha gbogbo, li Oluwa wi.

33. Hasori yio di ibugbe fun ọ̀wawa, ahoro titi lai: kì o si ẹnikan ti yio joko nibẹ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀.

34. Ọ̀rọ Oluwa ti o tọ Jeremiah, woli, wá si Elamu, ni ibẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, wipe:

35. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o ṣẹ́ ọrun Elamu, ti iṣe olori agbara wọn.

Ka pipe ipin Jer 49