Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 46:10-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ṣugbọn ọjọ yi li ọjọ igbẹsan Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o le gbẹsan lara awọn ọta rẹ̀; idà yio si jẹ, yio si tẹ́ ẹ lọrun, a o si fi ẹ̀jẹ wọn mu u yo: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni irubọ ni ilẹ ariwa lẹba odò Euferate.

11. Goke lọ si Gileadi, ki o si mu ikunra, iwọ wundia, ọmọbinrin Egipti: li asan ni iwọ o lò ọ̀pọlọpọ õgùn; ọja-imularada kò si fun ọ.

12. Awọn orilẹ-ède ti gbọ́ itiju rẹ, igbe rẹ si ti kún ilẹ na: nitori alagbara ọkunrin ti kọsẹ lara alagbara, ati awọn mejeji si jumọ ṣubu pọ̀.

13. Ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun Jeremiah, woli, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli wá lati kọlu ilẹ Egipti.

14. Ẹ sọ ọ ni Egipti, ki ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Migdoli, ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Nofu ati Tafanesi: ẹ wipe, duro lẹsẹsẹ, ki o si mura, nitori idà njẹrun yi ọ kakiri.

15. Ẽṣe ti a fi gbá awọn akọni rẹ lọ? nwọn kò duro, nitori Oluwa le wọn.

16. A sọ awọn ti o kọsẹ di pupọ, lõtọ, ẹnikini ṣubu le ori ẹnikeji: nwọn si wipe, Dide, ẹ jẹ ki a pada lọ sọdọ awọn enia wa, ati si ilẹ ti a bi wa, kuro lọwọ idá aninilara.

17. Nwọn kigbe nibẹ; Farao, ọba Egipti ti ṣegbe: on ti kọja akoko ti a dá!

18. Bi emi ti wà, li Ọba, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, nitõtọ gẹgẹ bi Tabori lãrin awọn oke, ati gẹgẹ bi Karmeli lẹba okun, bẹ̃ni on o de.

19. Iwọ, ọmọbinrin ti ngbe Egipti, pèse ohun-èlo ìrin-ajo fun ara rẹ: nitori Nofu yio di ahoro, a o si fi joná, laini olugbe.

20. Ẹgbọrọ malu ti o dara pupọ ni Egipti, lõtọ, iparun de, o de lati ariwa!

21. Awọn ologun rẹ̀ ti a fi owo bẹ̀, dabi akọmalu abọpa lãrin rẹ̀; awọn wọnyi pẹlu yi ẹhin pada; nwọn jumọ sa lọ pọ: nwọn kò duro, nitoripe ọjọ wàhala wọn de sori wọn, àkoko ibẹwo wọn.

22. Ohùn inu rẹ̀ yio lọ gẹgẹ bi ti ejo; nitori nwọn o lọ pẹlu agbara; pẹlu àkeke lọwọ ni nwọn tọ̀ ọ wá bi awọn akégi.

23. Nwọn o ke igbo rẹ̀ lulẹ, li Oluwa wi, nitori ti a kò le ridi rẹ̀; nitoripe nwọn pọ̀ jù ẹlẹnga lọ, nwọn si jẹ ainiye.

24. Oju yio tì ọmọbinrin Egipti; a o fi i le ọwọ awọn enia ariwa.

25. Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe; Wò o, emi o bẹ̀ Amoni ti No, ati Farao, ati Egipti wò, pẹlu awọn ọlọla wọn, ati awọn ọba wọn; ani Farao ati gbogbo awọn ti o gbẹkẹ le e:

26. Emi o si fi wọn le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati le ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀: lẹhin na, a o si mã gbe inu rẹ̀, gẹgẹ bi ìgba atijọ, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 46