Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 42:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni gbogbo awọn olori ogun, ati Johanani, ọmọ Karea, ati Jesaniah, ọmọ Hoṣaiah, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere de ẹni-nla, nwọn wá,

2. Nwọn si sọ fun Jeremiah woli, pe, Awa bẹ ọ, jẹ ki ẹ̀bẹ wa ki o wá siwaju rẹ, ki o si gbadura fun wa si Oluwa Ọlọrun rẹ, ani fun gbogbo iyokù yi; (nitori lati inu ọ̀pọlọpọ, diẹ li awa kù, gẹgẹ bi oju rẹ ti ri wa:)

3. Ki Oluwa Ọlọrun rẹ le fi ọ̀na hàn wa ninu eyi ti awa iba rìn, ati ohun ti awa iba ṣe.

4. Jeremiah, woli, si wi fun wọn pe, emi gbọ́; wò o, emi o gbadura si Oluwa Ọlọrun nyin gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin; yio si ṣe, pe ohunkohun ti Oluwa yio fi da nyin lohùn emi o sọ ọ fun nyin; emi kì o ṣẹ nkankan kù fun nyin.

5. Nwọn si wi fun Jeremiah pe, ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹri otitọ ati ododo lãrin wa, bi awa kò ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa, Ọlọrun rẹ, yio rán ọ si wa.

6. Iba ṣe rere, iba ṣe ibi, awa o gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, sọdọ ẹniti awa rán ọ: ki o le dara fun wa, bi awa ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.

7. O si ṣe lẹhin ọjọ mẹwa li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá.

8. Nigbana ni o pè Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere titi de ẹni-nla.

9. O si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, sọdọ ẹniti ẹnyin rán mi, lati mu ẹ̀bẹ nyin wá siwaju rẹ̀;

10. Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin.

Ka pipe ipin Jer 42