Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 39:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Mu u, ki o si bojuto o, má si ṣe e ni ibi kan; ṣugbọn gẹgẹ bi on ba ti sọ fun ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe fun u.

13. Bẹ̃ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ati Nebuṣaṣbani, olori iwẹfa, ati Nergali Ṣareseri, olori amoye, ati gbogbo ijoye ọba Babeli, si ranṣẹ,

14. Ani nwọn ranṣẹ nwọn si mu Jeremiah jade ni àgbala ile-tubu, nwọn si fi fun Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, pe ki o mu u lọ si ile: bẹ̃ni o ngbe ãrin awọn enia.

15. Ọrọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, nigbati a se e mọ ninu àgbala ile-túbu, wipe,

16. Lọ, ki o si sọ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o mu ọ̀rọ mi wá sori ilu yi fun ibi, kì isi ṣe fun rere; nwọn o si ṣẹ niwaju rẹ li ọjọ na.

17. Ṣugbọn emi o gbà ọ li ọjọ na, li Oluwa wi: a kì o si fi ọ le ọwọ awọn enia na ti iwọ bẹ̀ru.

18. Nitori emi o gbà ọ là nitõtọ, iwọ kì o si ti ipa idà ṣubu, ṣugbọn ẹ̀mi rẹ yio jẹ bi ikogun fun ọ: nitoripe iwọ ti gbẹkẹ rẹ le mi, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 39