Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 39:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati a kó Jerusalemu (li ọdun kẹsan Sedekiah, ọba Juda, li oṣu kẹwa ni Nebukadnessari, ọba Babeli, ati gbogbo ogun rẹ̀ wá si Jerusalemu, nwọn si dó tì i.

2. Ati li ọdun kọkanla Sedekiah, li oṣu kẹrin, li ọjọ keṣan oṣu li a fọ ilu na.)

3. Gbogbo awọn ijoye ọba Babeli si wọle, nwọn si joko li ẹnu-bode ãrin, ani Nergali-Ṣareseri, Samgari-nebo, Sarsikimu, olori iwẹfa, Nergali-Ṣareseri, olori amoye, pẹlu gbogbo awọn ijoye ọba Babeli iyokù.

4. O si ṣe, nigbati Sedekiah, ọba Juda, ati gbogbo awọn ologun ri wọn, nigbana ni nwọn sá, nwọn si jade kuro ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ọgbà ọba ati ẹnu-bode lãrin odi mejeji, nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.

5. Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa wọn, nwọn si ba Sedekiah, ọba, ni pẹtẹlẹ Jeriko; nigbati nwọn si mu u, nwọn mu u goke wá sọdọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Ribla ni ilẹ Hamati, nibiti o sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.

6. Nigbana ni ọba Babeli pa awọn ọmọ Sedekiah ni Ribla, niwaju rẹ̀; ọba Babeli si pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu.

7. Pẹlupẹlu o fọ Sedekiah li oju, o si fi ẹ̀wọn dè e, lati mu u lọ si Babeli.

8. Awọn ara Kaldea si fi ile ọba ati ile awọn enia joná, nwọn si wó odi Jerusalemu lulẹ.

9. Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ti ya lọ, ti o ya sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn enia iyokù ti o kù.

10. Ṣugbọn Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu diẹ ninu awọn enia, ani awọn talaka ti kò ni nkan rara, joko ni ilẹ Juda, o si fi ọgba-àjara ati oko fun wọn li àkoko na.

Ka pipe ipin Jer 39