Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 38:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Ṣefatiah, ọmọ Mattani, ati Gedaliah, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemiah, ati Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ ti Jeremiah ti sọ fun gbogbo enia, wipe,

2. Bayi li Oluwa wi pe, ẹniti o ba joko ni ilu yi yio kú nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-àrun, ẹniti o ba si jade tọ̀ awọn ara Kaldea lọ yio yè; a o si fi ẹmi rẹ́ fun u bi ikogun, yio si yè.

3. Bayi li Oluwa wi pe, lõtọ a o fi ilu yi le ọwọ ogun ọba Babeli, ẹniti yio si kó o.

4. Awọn ijoye si sọ fun ọba pe, Jẹ ki a pa ọkunrin yi: nitori bayi li o mu ọwọ awọn ologun ti o kù ni ilu yi rọ, pẹlu ọwọ gbogbo enia, ni sisọ iru ọ̀rọ bayi fun wọn: nitori ọkunrin yi kò wá alafia awọn enia yi, bikoṣe ibi wọn.

5. Sedekiah ọba, si wipe, Wò o, on wà li ọwọ nyin, nitori ọba kò le iṣe ohun kan lẹhin nyin.

6. Nwọn si mu Jeremiah, nwọn si sọ ọ sinu iho Malkiah ọmọ Hammeleki, ti o wà li agbala ile-túbu: nwọn fi okun sọ Jeremiah kalẹ sisalẹ. Omi kò si si ninu iho na, bikoṣe ẹrẹ̀: Jeremiah si rì sinu ẹrẹ̀ na.

7. Nigbati Ebedmeleki, ara Etiopia, iwẹfa kan, ti o wà ni ile ọba, gbọ́ pe, nwọn fi Jeremiah sinu iho: ọba joko nigbana li ẹnu-bode Benjamini;

8. Ebedmeleki si jade lati ile ọba lọ, o si sọ fun ọba wipe,

9. Oluwa mi, ọba! awọn ọkunrin wọnyi ti ṣe ibi ni gbogbo eyi ti nwọn ti ṣe si Jeremiah woli pe, nwọn ti sọ ọ sinu iho; ebi yio si fẹrẹ pa a kú ni ibi ti o gbe wà: nitori onjẹ kò si mọ ni ilu.

10. Nigbana ni ọba paṣẹ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe, Mu ọgbọ̀n enia lọwọ lati ihin lọ, ki o si fà Jeremiah soke lati inu iho, ki o to kú.

Ka pipe ipin Jer 38