Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 36:28-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Tun mu iwe kiká miran, ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ iṣaju sinu rẹ̀ ti o wà ninu iwe-kiká ekini, ti Jehoiakimu, ọba Juda, ti fi joná.

29. Iwọ o si sọ niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti fi iwe-kiká yi joná o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi kọwe sinu rẹ̀, pe: Lõtọ ọba Babeli yio wá yio si pa ilẹ yi run, yio si pa enia ati ẹran run kuro ninu rẹ̀?

30. Nitorina bayi li Oluwa wi niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, On kì yio ni ẹniti yio joko lori itẹ Dafidi: a o si sọ okú rẹ̀ nù fun oru li ọsan, ati fun otutu li õru.

31. Emi o si jẹ on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ niya, nitori aiṣedede wọn; emi o si mu wá sori wọn, ati sori awọn olugbe Jerusalemu, ati sori awọn ọkunrin Juda, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn, ṣugbọn nwọn kò gbọ́.

32. Nigbana ni Jeremiah mu iwe-kiká miran, o si fi i fun Baruku, akọwe, ọmọ Neriah; ẹniti o kọwe sinu rẹ̀ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ iwe ti Jehoiakimu, ọba Juda ti sun ninu iná: a si fi ọ̀rọ pupọ bi iru eyi kún ọ̀rọ iwe na pẹlu.

Ka pipe ipin Jer 36