Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 36:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ọba si rán Jehudu lati lọ mu iwe-kiká na wá: on si mu u jade lati inu iyara Eliṣama, akọwe. Jehudu si kà a li eti ọba, ati li eti gbogbo awọn ijoye, ti o duro tì ọba.

22. Ọba si ngbe ile igba-otutu li oṣu kẹsan: ina si njo niwaju rẹ̀ ninu idana.

23. O si ṣe, nigbati Jehudu ti kà ewe mẹta tabi mẹrin, ọba fi ọbẹ ke iwe na, o si sọ ọ sinu iná ti o wà ninu idaná, titi gbogbo iwe-kiká na fi joná ninu iná ti o wà lori idaná.

24. Sibẹ nwọn kò warìri, nwọn kò si fa aṣọ wọn ya, ani ọba, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti o gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi.

25. Ṣugbọn Elnatani ati Delaiah ati Gemariah bẹbẹ lọdọ ọba ki o máṣe fi iwe-kiká na joná, kò si fẹ igbọ́ ti wọn.

26. Ṣugbọn ọba paṣẹ fun Jerameeli, ọmọ Hameleki, ati Seraiah, ọmọ Asraeli, ati Ṣelemiah, ọmọ Abdeeli, lati mu Baruku akọwe, ati Jeremiah woli: ṣugbọn Oluwa fi wọn pamọ.

27. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá, lẹhin ti ọba ti fi iwe-kiká na ati ọ̀rọ ti Baruku kọ lati ẹnu Jeremiah wá joná, wipe,

28. Tun mu iwe kiká miran, ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ iṣaju sinu rẹ̀ ti o wà ninu iwe-kiká ekini, ti Jehoiakimu, ọba Juda, ti fi joná.

29. Iwọ o si sọ niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti fi iwe-kiká yi joná o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi kọwe sinu rẹ̀, pe: Lõtọ ọba Babeli yio wá yio si pa ilẹ yi run, yio si pa enia ati ẹran run kuro ninu rẹ̀?

Ka pipe ipin Jer 36