Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 35:8-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bayi li awa gbà ohùn Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa gbọ́ ninu gbogbo eyiti o palaṣẹ fun wa, ki a má mu ọti-waini ni gbogbo ọjọ wa, awa, awọn aya wa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa;

9. Ati ki a má kọ ile lati gbe; bẹ̃ni awa kò ni ọgba-ajara, tabi oko, tabi ohùn ọgbin.

10. Ṣugbọn awa ngbe inu agọ, a si gbọran, a si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jonadabu, baba wa, palaṣẹ fun wa.

11. O si ṣe, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli, goke wá si ilẹ na, ni awa wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si Jerusalemu, nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Kaldea, ati nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Siria: bẹ̃ni awa ngbe Jerusalemu.

12. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá wipe:

13. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Lọ, ki o si sọ fun awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu pe, Ẹnyin kì yio ha gbà ẹkọ lati feti si ọ̀rọ mi? li Oluwa wi.

14. Ọ̀rọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, ti o pa laṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o má mu ọti-waini, ni a mu ṣẹ; nwọn kò si mu ọti-waini titi di oni yi. Nitoriti nwọn gbọ́ ofin baba wọn, emi si ti nsọ̀rọ fun nyin, emi dide ni kutukutu, emi nsọ: ṣugbọn ẹnyin kò fetisi ti emi.

Ka pipe ipin Jer 35