Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 32:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ti o si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ agbara, ati ninà apa ati ẹ̀ru nla mu Israeli enia rẹ jade ni ilẹ Egipti.

22. Ti iwọ si ti fun wọn ni ilẹ yi, eyiti iwọ bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn, ilẹ ti nṣàn fun wara ati oyin;

23. Nwọn si wá, nwọn si ni i; ṣugbọn nwọn kò gbà ohùn rẹ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò rìn ninu ofin rẹ, nwọn kò ṣe gbogbo eyiti iwọ paṣẹ fun wọn lati ṣe: iwọ si pè gbogbo ibi yi wá sori wọn:

24. Wo o! odi ọta! nwọn sunmọ ilu lati kó o; a si fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea, ti mba a jà, niwaju idà, ati ìyan, àjakalẹ-àrun: ati ohun ti iwọ ti sọ, ṣẹ; si wò o, iwọ ri i.

25. Ṣugbọn iwọ ti sọ fun mi, Oluwa Ọlọrun! pe, Iwọ fi owo rà oko na fun ara rẹ, ki o si pe awọn ẹlẹri; sibẹ, a o fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea.

26. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá, wipe,

27. Wò o, emi li Oluwa, Ọlọrun gbogbo ẹran-ara: ohun kan ha wà ti o ṣòro fun mi bi?

28. Nitorina, bayi li Oluwa wi, Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, on o si kó o:

29. Ati awọn ara Kaldea, ti mba ilu yi jà, nwọn o wá, nwọn o si tẹ iná bọ̀ ilu yi, nwọn o si kun u, ati ile, lori orule eyiti nwọn ti nrubọ turari si Baali, ti nwọn si ti ndà ẹbọ ohun mimu fun ọlọrun miran, lati mu mi binu.

Ka pipe ipin Jer 32