Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 32:18-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Iwọ ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun, o si san aiṣedede awọn baba si aiya awọn ọmọ lẹhin wọn: Ọlọrun titobi, Alagbara! Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

19. Titobi ni igbimọ, ati alagbara ni iṣe; oju rẹ ṣí si gbogbo ọ̀na awọn ọmọ enia: lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀ ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀:

20. Ẹniti o gbe àmi ati iṣẹ-iyanu kalẹ ni Egipti, titi di oni yi, ati lara Israeli, ati lara enia miran: ti iwọ si ti ṣe orukọ fun ara rẹ, gẹgẹ bi o ti ri li oni yi.

21. Ti o si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ agbara, ati ninà apa ati ẹ̀ru nla mu Israeli enia rẹ jade ni ilẹ Egipti.

22. Ti iwọ si ti fun wọn ni ilẹ yi, eyiti iwọ bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn, ilẹ ti nṣàn fun wara ati oyin;

23. Nwọn si wá, nwọn si ni i; ṣugbọn nwọn kò gbà ohùn rẹ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò rìn ninu ofin rẹ, nwọn kò ṣe gbogbo eyiti iwọ paṣẹ fun wọn lati ṣe: iwọ si pè gbogbo ibi yi wá sori wọn:

24. Wo o! odi ọta! nwọn sunmọ ilu lati kó o; a si fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea, ti mba a jà, niwaju idà, ati ìyan, àjakalẹ-àrun: ati ohun ti iwọ ti sọ, ṣẹ; si wò o, iwọ ri i.

25. Ṣugbọn iwọ ti sọ fun mi, Oluwa Ọlọrun! pe, Iwọ fi owo rà oko na fun ara rẹ, ki o si pe awọn ẹlẹri; sibẹ, a o fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea.

26. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá, wipe,

27. Wò o, emi li Oluwa, Ọlọrun gbogbo ẹran-ara: ohun kan ha wà ti o ṣòro fun mi bi?

28. Nitorina, bayi li Oluwa wi, Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, on o si kó o:

29. Ati awọn ara Kaldea, ti mba ilu yi jà, nwọn o wá, nwọn o si tẹ iná bọ̀ ilu yi, nwọn o si kun u, ati ile, lori orule eyiti nwọn ti nrubọ turari si Baali, ti nwọn si ti ndà ẹbọ ohun mimu fun ọlọrun miran, lati mu mi binu.

30. Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda ti ṣe kiki ibi niwaju mi lati igba èwe wọn wá: nitori awọn ọmọ Israeli ti fi kiki iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu, li Oluwa wi.

31. Nitori ilu yi ti jẹ ohun ibinu ati irunu fun mi lati ọjọ ti nwọn ti kọ ọ wá titi di oni yi; tobẹ̃ ti emi o mu u kuro niwaju mi.

32. Nitori gbogbo ibi awọn ọmọ Israeli, ati awọn ọmọ Juda, ti nwọn ti ṣe lati mu mi binu, awọn, awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn, ati awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu.

Ka pipe ipin Jer 32