Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 3:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SA wò o, bi a wipe ọkunrin kan kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti aya na si kuro lọdọ rẹ̀, ti o si di aya ẹlomiran, ọkunrin na le tun tọ̀ ọ wá? ilẹ na kì yio di ibajẹ gidigidi? ṣugbọn iwọ ti ba ayanfẹ pupọ ṣe panṣaga, iwọ o tun tọ̀ mi wá! li Oluwa wi.

2. Gbe oju rẹ soke si ibi giga wọnnì, ki o si wò, nibo ni a kò ti bà ọ jẹ? Iwọ joko de wọn li oju ọ̀na, bi ara Arabia kan ni iju, iwọ si ti fi agbere ati ìwa buburu rẹ bà ilẹ na jẹ.

3. Nitorina emi fa ọ̀wara òjo sẹhin, kò si òjo arọkuro, sibẹ iwọ ni iwaju agbere, iwọ kọ̀ lati tiju.

4. Lõtọ lati isisiyi, iwọ kì yio ha pè mi pe, Baba mi! iwọ li ayanfẹ ìgba-ewe mi?

5. On o ha pa ibinu rẹ̀ mọ lailai? yio pa a mọ de opin? sa wò o, bayi ni iwọ ti wi, ṣugbọn iwọ ṣe ohun buburu li aidẹkun.

6. Oluwa si wi fun mi ni igba Josiah ọba, pe, Iwọ ri ohun ti Israeli apẹhinda ti ṣe? o ti gun ori oke giga gbogbo, ati labẹ gbogbo igi tutu, nibẹ li o ti ṣe panṣaga.

7. Emi si wipe, lẹhin ti o ti ṣe gbogbo ohun wọnyi tan, yio yipada si mi, ṣugbọn kò yipada, Juda alarekereke arabinrin rẹ̀ si ri i.

8. Emi si wò pe, nitori gbogbo wọnyi ti Israeli apẹhinda ti ṣe agbere, ti mo kọ̀ ọ silẹ ti emi si fun u ni iwe-ikọsilẹ, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò bẹ̀ru, o si nṣe agbere lọ pẹlu.

9. O si ṣe nitori okìki àgbere rẹ̀ li o fi bà ilẹ jẹ, ti o si ṣe àgbere tọ̀ okuta ati igi lọ.

10. Lẹhin gbogbo wọnyi, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò yipada si mi tọkàntọkàn ṣugbọn li agabagebe; li Oluwa wi.

11. Oluwa si wi fun mi pe, Israeli apẹhinda, ti dá ara rẹ̀ li are ju Juda alarekereke lọ.

12. Lọ ki o si kede ọ̀rọ wọnyi ni iha ariwa, ki o si wipe, Yipada iwọ Israeli, apẹhinda, li Oluwa wi, emi kì yio jẹ ki oju mi ki o korò si ọ; nitori emi ni ãnu, li Oluwa wi, emi kì o si pa ibinu mi mọ titi lai.

13. Sa jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ pe, iwọ ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe, o si tú ọ̀na rẹ ka fun awọn alejo labẹ igi tutu gbogbo, ṣugbọn ẹnyin kò gba ohùn mi gbọ́, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 3