Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 29:26-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Oluwa ti fi ọ jẹ oyè alufa ni ipo Jehoiada, alufa, ki ẹnyin ki o lè jẹ olutọju ni ile Oluwa, nitori olukuluku aṣiwere enia, ati ẹnikẹni ti o sọ asọtẹlẹ ki iwọ ki o le fi wọn sinu tubu ati sinu àba.

27. Njẹ nisisiyi, ẽṣe ti iwọ kò ba Jeremiah ti Anatoti wi, ẹniti o nsọ asọtẹlẹ fun nyin!

28. Nitorina li o ṣe ranṣẹ si wa ni Babeli, wipe, Akoko yio pẹ: ẹ kọ́ ile, ki ẹ si ma gbe inu wọn, ẹ si gbìn ọgbà, ki ẹ ma jẹ eso wọn.

29. Sefaniah, alufa, si ka iwe yi li eti Jeremiah woli.

30. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá wipe,

31. Ranṣẹ si gbogbo awọn igbekun, wipe, Bayi li Oluwa wi niti Ṣemaiah, ara Nehalami, nitoripe Ṣemaiah ti sọtẹlẹ fun nyin, ṣugbọn emi kò ran a, ti on si mu nyin gbẹkẹle eke:

32. Nitorina, bayi li Oluwa wi: Wò o, emi o bẹ Ṣemaiah, ara Nehalami, wò, ati iru-ọmọ rẹ̀; on kì yio ni ọkunrin kan lati ma gbe ãrin enia yi; bẹ̃ni kì yio ri rere na ti emi o ṣe fun awọn enia mi, li Oluwa wi; nitoripe o ti ṣọ̀tẹ si Oluwa.

Ka pipe ipin Jer 29