Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 28:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Jeremiah woli si wi fun Hananiah woli niwaju awọn alufa ati niwaju gbogbo enia, ti o duro ni ile Oluwa pe:

6. Jeremiah woli si wipe, Amin: ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃: ki Oluwa ki o mu ọ̀rọ rẹ ti iwọ sọ asọtẹlẹ ṣẹ, lati mu ohun-elo ile Oluwa ati gbogbo igbekun pada, lati Babeli wá si ibi yi.

7. Ṣugbọn nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ yi ti mo sọ si eti rẹ ati si eti enia gbogbo.

8. Awọn woli ti o ti ṣaju mi, ati ṣaju rẹ ni igbãni sọ asọtẹlẹ pupọ, ati si ijọba nla niti ogun, ati ibi, ati ajakalẹ-arun.

9. Woli nì ti o sọ asọtẹlẹ alafia, bi ọ̀rọ woli na ba ṣẹ, nigbana ni a o mọ̀ woli na pe, Oluwa rán a nitõtọ.

10. Nigbana ni Hananiah woli mu àjaga kuro li ọrùn Jeremiah woli o si ṣẹ́ ẹ.

11. Hananiah si wi niwaju gbogbo enia pe, Bayi li Oluwa wi; Bẹ̃ gẹgẹ li emi o ṣẹ́ ajaga Nebukadnessari, ọba Babeli, kuro li ọrùn orilẹ-ède gbogbo ni igba ọdun meji. Jeremiah woli si ba ọ̀na tirẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Jer 28