Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 28:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Hananiah si wi niwaju gbogbo enia pe, Bayi li Oluwa wi; Bẹ̃ gẹgẹ li emi o ṣẹ́ ajaga Nebukadnessari, ọba Babeli, kuro li ọrùn orilẹ-ède gbogbo ni igba ọdun meji. Jeremiah woli si ba ọ̀na tirẹ̀ lọ.

12. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah woli wá lẹhin igbati Hananiah woli ti ṣẹ́ ajaga kuro li ọrùn Jeremiah woli, wipe,

13. Lọ isọ fun Hananiah wipe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti ṣẹ́ àjaga igi; ṣugbọn iwọ o si ṣe àjaga irin ni ipo wọn.

14. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi: emi ti fi ajaga irin si ọrùn gbogbo orilẹ-ède wọnyi, ki nwọn ki o sin Nebukadnessari, ọba Babeli, nwọn o si sin i, emi si fi ẹranko igbẹ fun u pẹlu.

15. Nigbana ni Jeremiah, woli, wi fun Hananiah, woli, pe, Gbọ́ nisisiyi, Hananiah; Oluwa kò rán ọ; ṣugbọn iwọ jẹ ki enia yi ki o gbẹkẹle eke.

16. Nitorina bayi li Oluwa wi; Sa wo o, emi o ta ọ nù kuro loju aiye: li ọdun yi ni iwọ o kú, nitori iwọ ti sọ̀rọ iṣọtẹ si Oluwa.

17. Bẹ̃ni Hananiah woli si kú li ọdun na li oṣu keje.

Ka pipe ipin Jer 28