Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 27:9-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nitorina ẹ máṣe fi eti si awọn woli nyin, tabi si awọn alafọṣẹ nyin, tabi si awọn alála, tabi si awọn oṣo nyin, tabi awọn ajẹ nyin ti nsọ fun nyin pe, Ẹnyin kì o sin ọba Babeli:

10. Nitori nwọn sọ-asọtẹlẹ eke fun nyin, lati mu nyin jina réré kuro ni ilẹ nyin, ki emi ki o lè lé nyin jade, ti ẹnyin o si ṣegbe.

11. Ṣugbọn orilẹ-ède na ti o mu ọrùn rẹ̀ wá si abẹ àjaga ọba Babeli, ti o si sìn i, on li emi o jẹ ki o joko ni ilẹ wọn, li Oluwa wi, yio si ro o, yio si gbe ibẹ.

12. Emi si wi fun Sedekiah, ọba Juda, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi, pe, Ẹ mu ọrùn nyin si abẹ àjaga ọba Babeli, ki ẹ sin i, pẹlu awọn enia rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin o yè.

13. Ẽṣe ti ẹnyin o kú, iwọ, ati enia rẹ, nipa idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, bi Oluwa ti sọ si orilẹ-ède ti kì yio sin ọba Babeli.

14. Ẹ máṣe gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nwọn nsọ fun nyin wipe, Ẹnyin kì yio sin ọba Babeli, nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.

15. Nitori emi kò rán wọn, li Oluwa wi, ṣugbọn nwọn nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi: ki emi ki o lè lé nyin jade, ki ẹ ṣegbe, ẹnyin, pẹlu awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ fun nyin.

16. Pẹlupẹlu emi sọ fun awọn alufa ati fun gbogbo enia yi wipe, Bayi li Oluwa wi, Ẹ má gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin wipe, Sa wò o, ohun-èlo ile Oluwa li a o mu pada li aipẹ nisisiyi lati Babeli wá: nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.

17. Ẹ máṣe gbọ́ ti wọn; ẹ sin ọba Babeli, ẹ si yè: ẽṣe ti ilu yi yio fi di ahoro?

Ka pipe ipin Jer 27