Pẹlupẹlu emi sọ fun awọn alufa ati fun gbogbo enia yi wipe, Bayi li Oluwa wi, Ẹ má gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin wipe, Sa wò o, ohun-èlo ile Oluwa li a o mu pada li aipẹ nisisiyi lati Babeli wá: nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.