Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 22:5-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ṣugbọn bi ẹnyin kì yio ba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, Emi fi emitikarami bura, li Oluwa wi, pe, ile yi yio di ahoro.

6. Nitori bayi li Oluwa wi fun ile ọba Juda; Gileadi ni iwọ si mi, ori Lebanoni: sibẹ, lõtọ emi o sọ ọ di aginju, ati ilu ti a kò gbe inu wọn.

7. Emi o ya awọn apanirun sọtọ fun ọ, olukuluku pẹlu ihamọra rẹ̀: nwọn o si ke aṣayan igi kedari rẹ lulẹ, nwọn o si sọ wọn sinu iná.

8. Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio rekọja lẹba ilu yi, nwọn o wi, ẹnikan fun ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Oluwa ṣe bayi si ilu nla yi?

9. Nigbana ni nwọn o dahùn pe, nitoriti nwọn ti kọ̀ majẹmu Oluwa Ọlọrun wọn silẹ; ti nwọn fi ori balẹ fun ọlọrun miran, nwọn si sìn wọn.

10. Ẹ máṣe sọkun fun okú, bẹ̃ni ki ẹ máṣe pohùnrere rẹ̀, ṣugbọn ẹ sọkun ẹ̀dun fun ẹniti o nlọ, nitori kì yio pada wá mọ, kì yio si ri ilẹ rẹ̀ mọ.

11. Nitori bayi li Oluwa wi fun Ṣallumu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ti o jọba ni ipo Josiah, baba rẹ̀, ti o jade kuro nihin pe, On kì yio pada wá mọ.

12. Ṣugbọn yio kú ni ibi ti a mu u ni igbèkun lọ, kì yio si ri ilẹ yi mọ.

13. Egbe ni fun ẹniti o kọ́ ilẹ rẹ̀, ti kì iṣe nipa ododo, ati iyẹwu rẹ̀, ti kì iṣe nipa ẹ̀tọ́: ti o lò iṣẹ ọwọ aladugbo rẹ̀ lọfẹ, ti kò fi ere iṣẹ rẹ̀ fun u.

14. Ti o wipe, emi o kọ ile ti o ni ibò fun ara mi, ati iyẹwu nla, ti o ke oju ferese fun ara rẹ̀, ti o fi igi kedari bò o, ti o si fi ajẹ̀ kùn u.

15. Iwọ o ha jọba, nitori iwọ fi igi kedari dije? baba rẹ kò ha jẹ, kò ha mu? o si ṣe idajọ ati ododo, nitorina o dara fun u.

16. O dajọ ọ̀ran talaka ati alaini; o dara fun u: bi ãti mọ̀ mi kọ́ eyi? li Oluwa wi.

17. Ṣugbọn oju rẹ̀ ati ọkàn rẹ kì iṣe fun ohunkohun bikoṣe ojukokoro rẹ, ati lati ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, ati lati ṣe ininilara ati agbara.

18. Nitorina bayi li Oluwa wi nitori Jehoiakimu ọmọ Josiah, ọba Juda, nwọn kì yio ṣọ̀fọ fun u, wipe, Oṣe! arakunrin mi! tabi Oṣe! arabinrin mi! nwọn kì o ṣọ̀fọ fun u pe, Oṣe, oluwa! tabi Oṣe, ọlọla!

19. A o sin i ni isinkú kẹtẹkẹtẹ, ti a wọ́ ti a si sọ junù kuro ni ẹnu-bode Jerusalemu.

20. Goke lọ si Lebanoni, ki o si ke, ki o si gbe ohùn rẹ soke ni Baṣani, ki o kigbe lati Abarimu, nitori a ti ṣẹ́ gbogbo olufẹ rẹ tutu,

21. Emi ti ba ọ sọ̀rọ ni ìgba ire rẹ; iwọ wipe, emi kì yio gbọ́. Eyi ni ìwa rẹ lati igba ewe rẹ wá, ti iwọ kò si gba ohùn mi gbọ.

22. Ẹfũfu yio fẹ gbogbo oluṣọ-agutan rẹ lọ, ati awọn olufẹ rẹ yio lọ si ìgbekun: nitõtọ, ni wakati na ni oju yio tì ọ, iwọ o si dãmu nitori gbogbo buburu rẹ.

23. Iwọ, olugbe Lebanoni, ti o tẹ́ itẹ si ori igi kedari, iwọ o ti jẹ otoṣi to, nigbati irora ba deba ọ, irora bi obinrin ti nrọbi!

24. Bi emi ti wà, li Oluwa wi, bi Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, tilẹ jẹ oruka-èdidi lọwọ ọtun mi, sibẹ̀ emi o fà ọ tu kuro nibẹ.

Ka pipe ipin Jer 22