Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 2:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

2. Lọ, ki o si ke li eti Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ranti rẹ, iṣeun igbà ọmọde rẹ, ifẹ igbeyawo rẹ, nigbati iwọ tẹle mi ni iju, ni ilẹ ti a kì igbin si.

3. Mimọ́ ni Israeli fun Oluwa, akọso eso oko rẹ̀, ẹnikẹni ti o fi jẹ yio jẹbi; ibi yio si wá si ori wọn, li Oluwa wi.

4. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ara-ile Jakobu, ati gbogbo iran ile Israeli:

5. Bayi li Oluwa wi: Aiṣedede wo li awọn baba nyin ri lọwọ mi ti nwọn lọ jina kuro lọdọ mi, ti nwọn si tẹle asan, ti nwọn si di enia asan?

6. Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si.

7. Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira:

Ka pipe ipin Jer 2