Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 19:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAYI li Oluwa wi, Lọ, rà igo amọ ti amọkoko, si mu ninu awọn àgba enia, ati awọn àgba alufa;

2. Ki o si lọ si afonifoji ọmọ Hinnomu ti o wà niwaju ẹnu-bode Harsiti, nibẹ ni ki o si kede gbogbo ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ.

3. Ki o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda, ati olugbe Jerusalemu; Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi: sa wò o, emi o mu ibi wá sihin yi, eyiti eti gbogbo awọn ti o ba gbọ́ ọ, yio ho.

4. Nitori nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn ti sọ ihín yi di iyapa, nwọn si ti sun turari ninu rẹ̀ fun awọn ọlọrun miran, eyiti awọn, tabi awọn baba wọn kò mọ̀ ri, tabi awọn ọba Juda, nwọn si ti fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ kún ibi yi;

Ka pipe ipin Jer 19