Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 16:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo dakẹ ni ihinyi loju nyin ati li ọjọ nyin.

10. Yio si ṣe, nigbati iwọ o ba fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi han enia yi, nwọn o wi fun ọ pe, Ẽṣe ti Oluwa fi sọ̀rọ gbogbo ohun buburu nla yi si wa, tabi kini aiṣedede wa? tabi ẹ̀ṣẹ kini awa da si Oluwa Ọlọrun wa?

11. Nigbana ni iwọ o wi fun wọn pe, Nitoripe awọn baba nyin ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, ti nwọn si rìn tọ̀ ọlọrun miran lọ, ti nwọn si sìn wọn, ti nwọn si foribalẹ fun wọn, ti nwọn kọ̀ mi silẹ, ti nwọn kò pa ofin mi mọ;

12. Ati pẹlu pe, ẹnyin ti ṣe buburu jù awọn baba nyin lọ: nitorina sa wò o, ẹnyin rìn olukuluku nyin, ni agidi ọkàn buburu rẹ̀, ki ẹnyin ki o má ba gbọ́ temi:

13. Emi o si ta nyin nu kuro ni ilẹ yi, sinu ilẹ ti ẹnyin kò mọ̀, ẹnyin tabi awọn baba nyin, nibẹ li ẹnyin o sin ọlọrun miran, lọsan ati loru nibiti emi kì yio ṣe oju-rere fun nyin.

Ka pipe ipin Jer 16