Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 16:2-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Iwọ kò gbọdọ ni aya, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ni ihinyi.

3. Nitori bayi li Oluwa wi niti ọmọkunrin ati ọmọbinrin ti a bi ni ihinyi, ati niti awọn iya wọn ti o bi wọn, ati niti awọn baba wọn ti o bi wọn ni ilẹ yi.

4. Nwọn o kú ikú àrun; a kì yio ṣọ̀fọ wọn; bẹ̃ni a kì yio si sin wọn; nwọn o si di àtan lori ilẹ: a o fi idà ati ìyan run wọn, ati okú wọn yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ.

5. Nitori bayi li Oluwa wi, máṣe wọ inu ile ãwẹ̀, bẹ̃ni ki iwọ máṣe lọ sọ̀fọ, tabi lọ pohùnrere ẹkun wọn; nitori emi ti mu alafia mi kuro lọdọ enia yi, li Oluwa wi, ani ãnu ati iyọ́nu.

6. Ati ẹni-nla ati ẹni-kekere yio kú ni ilẹ yi, a kì yio sin wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio fá ori wọn nitori wọn.

7. Bẹ̃ni ẹnikan kì yio bu àkara lati ṣọ̀fọ fun wọn, lati tù wọn ninu nitori okú; bẹ̃ni ẹnikan kì yio fun wọn ni ago itunu mu nitori baba wọn, tabi nitori iya wọn.

8. Iwọ kò gbọdọ lọ sinu ile àse, lati joko pẹlu wọn lati jẹ ati lati mu.

9. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo dakẹ ni ihinyi loju nyin ati li ọjọ nyin.

10. Yio si ṣe, nigbati iwọ o ba fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi han enia yi, nwọn o wi fun ọ pe, Ẽṣe ti Oluwa fi sọ̀rọ gbogbo ohun buburu nla yi si wa, tabi kini aiṣedede wa? tabi ẹ̀ṣẹ kini awa da si Oluwa Ọlọrun wa?

Ka pipe ipin Jer 16